Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,láti máa wá ọtí líle kiri,tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!

12. Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13. Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.

14. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,ó ti yanu kalẹ̀.Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.

15. A tẹ eniyan lórí ba,a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀.

16. Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogunni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodoỌlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo.

17. Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọnàwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.

18. Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.

Ka pipe ipin Aisaya 5