Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 49:10-25 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ebi kò ní pa wọ́n,òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.

11. “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.

12. Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá,láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.”

13. Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀,ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin,nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.

14. Sioni ń wí pé,“OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,Oluwa mi ti gbàgbé mi.”

15. OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú?Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀?Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé.Èmi kò ní gbàgbé rẹ.

16. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi,àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.

17. “Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá,àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ.

18. Gbójú sókè, kí o wò yíká,gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá.OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé,o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara.O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀.

19. “Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀,ati àwọn tí ó ti di ahoro,yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá,a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ.

20. Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹyóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé,‘Ibí yìí kéré jù fún wa,fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’

21. O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé,‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi?Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn,mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú.Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà?Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù,níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ”

22. OLUWA Ọlọrun ní,“Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè.N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan,wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọnwọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká.

23. Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba,àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá,ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ,wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá.O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA,ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.”

24. Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára,tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan?

25. OLUWA ní:“Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára,tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan.N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà,n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là.

Ka pipe ipin Aisaya 49