Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 43:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;

17. ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà.

18. ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.

19. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

20. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:

21. Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,kí wọ́n lè kéde ògo mi.

22. “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

23. Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.

24. Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.

25. Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,nítorí ti ara mi;n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.

26. “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;ẹ ro ẹjọ́ tiyín,kí á lè da yín láre.

27. Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.

28. Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun;mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”

Ka pipe ipin Aisaya 43