Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 42:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì,títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”

5. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ;ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.

6. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo,mo ti di ọwọ́ rẹ mú,mo sì pa ọ́ mọ́.Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé,mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;

7. kí o lè la ojú àwọn afọ́jú,kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́,kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

8. “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi;n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn,n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère.

9. Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá,àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii.Kí wọn tó yọjú jáde rárá,ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.”

10. Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA;ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé.Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun;ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn.

11. Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè,ati àwọn abúlé agbègbè Kedari;kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀,kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè.

Ka pipe ipin Aisaya 42