Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 42:22-25 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè,a sì ti kó wọn lẹ́rù,a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀,a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀,a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé:“Ẹ dá wọn pada.”

23. Èwo ninu yín ló fetí sí èyí,tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la?

24. Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́,ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́?Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni,ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀;tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.

25. Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun,ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n.Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e;iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n.

Ka pipe ipin Aisaya 42