Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 41:2-17 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.

3. A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.

4. Ta ló ṣe èyí?Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.

5. “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.

6. Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́,ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’

7. Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjúẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ,Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’Wọ́n kàn án ní ìṣó,ó le dáradára, kò le mì.

8. “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi,Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.

9. Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’

10. Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.

11. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ runni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,wọn óo sì ṣègbé.

12. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,o kò ní rí wọn.Àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóo di òfo patapata.

13. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,èmi ni mo sọ fún ọ pékí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”

14. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,ẹ̀yin ọmọ Israẹli,OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.

15. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,tí ó mú, tí ó sì ní eyín,ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.

16. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWAẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.

17. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 41