Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 41:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi.

19. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.

20. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”

21. OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.

22. Ẹ mú wọn wá,kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;kí á lè mọ àyọrísí wọn,tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”

23. OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá.

24. Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín.

25. Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,ó sì ti dé.Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.

26. Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

27. Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.

28. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan,tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè.

29. Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn,òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn:Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.”

Ka pipe ipin Aisaya 41