Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 41:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,tí ó mú, tí ó sì ní eyín,ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.

16. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWAẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.

17. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.

18. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi.

19. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.

20. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”

21. OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.

22. Ẹ mú wọn wá,kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;kí á lè mọ àyọrísí wọn,tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”

23. OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá.

24. Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín.

25. Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,ó sì ti dé.Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.

26. Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

27. Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Aisaya 41