Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 40:4-22 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.

5. Ògo OLUWA yóo farahàn,gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”

6. Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”Mo bá bèèrè pé,“Igbe kí ni kí n ké?”Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.

7. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.Dájúdájú koríko ni eniyan.

8. Koríko a máa rọ,òdòdó a sì máa rẹ̀;ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.”

9. Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni,kí o máa kéde ìyìn rere.Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu,ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rereké sókè má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlú Juda pé,“Ẹ wo Ọlọrun yín.”

10. Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbáraipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso.Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

11. Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan.Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀,yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀.Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.

12. Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun?Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run,Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayésinu òṣùnwọ̀n?Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n?

13. Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA,ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14. Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye,ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́,tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀,tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án?

15. Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi,ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n.Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè.

16. Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun.

17. Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀,wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n.

18. Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe;tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bòtí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún?

20. Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ,a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà.

21. Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?Ẹ kò sì tíì gbọ́?Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:

22. Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 40