Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 40:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu,ẹ tu àwọn eniyan mi ninu.

2. Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí,a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í.OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

3. Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé,“Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù,ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀.

4. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.

5. Ògo OLUWA yóo farahàn,gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”

6. Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”Mo bá bèèrè pé,“Igbe kí ni kí n ké?”Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.

7. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.Dájúdájú koríko ni eniyan.

8. Koríko a máa rọ,òdòdó a sì máa rẹ̀;ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.”

9. Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni,kí o máa kéde ìyìn rere.Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu,ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rereké sókè má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlú Juda pé,“Ẹ wo Ọlọrun yín.”

10. Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbáraipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso.Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 40