Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 4:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù.

3. Eniyan mímọ́ ni a óo máa pe àwọn tí wọ́n bá kù ní Sioni, àní, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn tí a bá kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pé wọ́n wà láàyè ní Jerusalẹmu.

4. Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́,

5. ní ọ̀sán, yóo mú kí ìkùukùu bo gbogbo òkè Sioni ati àwọn tí ó ń péjọ níbẹ̀; ní alẹ́, yóo sì fi èéfín ati ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ bò wọ́n. Ògo OLUWA yóo bò wọ́n bí àtíbàbà ati ìbòrí.

6. Yóo dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ oòrùn lọ́sàn-án, yóo jẹ́ ibi ìsásí ati ààbò fún wọn lọ́wọ́ ìjì ati òjò.

Ka pipe ipin Aisaya 4