Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 37:29-38 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Nítorí pé ò ń bá mi bínú,mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá.

30. “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀.

31. Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso.

32. Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí.

33. “Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í.

34. Ọ̀nà tí ọba Asiria gbà wá ni yóo gbà pada lọ, kò ní fi ẹsẹ̀ kan inú ìlú yìí.

35. N óo dáàbò bo ìlú yìí, n óo sì gbà á sílẹ̀ nítorí tèmi ati nítorí Dafidi iranṣẹ mi.’ ”

36. Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti.

37. Senakeribu ọba Asiria bá pada sílé, ó ń lọ gbé ìlú Ninefe.

38. Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 37