Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 37:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ.

2. Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi.

3. Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi.

4. Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ”

5. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya,

6. Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7. Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.Nígbà tí ó bá dé ilén óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ”

Ka pipe ipin Aisaya 37