1. O gbé! Ìwọ tí ń panirun,tí ẹnìkan kò parun,ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́.Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró,nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run;nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀,nígbà náà ni a óo dà ọ́.
2. Ṣàánú wa OLUWA,ìwọ ni a dúró tí à ń wò.Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ,sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro.
3. Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá,wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀.
4. A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko,àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko.
5. A gbé OLUWA ga!Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni.
6. Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.
7. Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
8. Òpópó ọ̀nà ṣófo,àwọn èrò kò rìn mọ́;wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;wọ́n kò sì ka eniyan sí.
9. Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.