Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 32:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò;kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀.

12. Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára,ati nítorí àwọn àjàrà eléso;

13. nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi.Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀,

14. nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin,ìlú yóo tú, yóo di ahoro.Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae,yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.

15. Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí,títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wátítí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso,tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó.

16. A óo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà,ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo.

17. Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia,ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa,ati igbẹkẹle OLUWA títí lae.

18. Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia,ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà.

19. Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀,a óo sì pa ìlú náà run patapata.

20. Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀,ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri.

Ka pipe ipin Aisaya 32