Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 32:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo,àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́.

2. Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jàWọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀,ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.

3. Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i,etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.

4. Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye,àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete.

5. A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki.

6. Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi.Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun,tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA;tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ,tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.

7. Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan.Wọn a máa pète ìkà,láti fi irọ́ pa àwọn talaka run,kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre.

8. Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere,ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn.

9. Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.

10. Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí iẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmúnítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá,èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́.

11. Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò;kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀.

12. Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára,ati nítorí àwọn àjàrà eléso;

Ka pipe ipin Aisaya 32