Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 31:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,wọn kìí ṣe Ọlọrun.Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọnwọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.

4. Nítorí OLUWA sọ fún mi pé,“Bí kinniun tabi ọmọ kinniunti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa,tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan,tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀,tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á;bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀,yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.

5. Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogunyóo dáàbò bo Jerusalẹmu,yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.”

6. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ.

7. Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadakaati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù,àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀.

8. Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan;idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run.Yóo sá lójú ogun,a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá.

Ka pipe ipin Aisaya 31