Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,tí wọ́n gbójú lé ẹṣinnítorí pé wọ́n lágbára!Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.