Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 3:16-26 BIBELI MIMỌ (BM)

16. OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

17. OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”

18. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn;

19. ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn.

20. Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn,

21. òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú,

22. ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò

23. ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.

24. Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,okùn yóo wà dípò ọ̀já;orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà.

25. Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín,àwọn akikanju yín yóo kú sógun.

26. Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu.Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò,tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 3