Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 3:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”

16. OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

17. OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”

18. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn;

19. ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn.

20. Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn,

21. òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú,

22. ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò

23. ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.

Ka pipe ipin Aisaya 3