Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 28:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.

2. Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbáratí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.

3. Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéragaàwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.

4. Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdótí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.

5. Ní ọjọ́ náà,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.

6. Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè.

7. Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.

8. Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí

9. Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?

Ka pipe ipin Aisaya 28