Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 28:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.

2. Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbáratí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.

3. Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéragaàwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.

4. Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdótí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.

5. Ní ọjọ́ náà,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 28