Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 27:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀,ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn;ó lé wọn jáde ní ìlú,bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn.

9. Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́,tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé:Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú,bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná;kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró.

10. Nítorí ìlú olódi ti di ahoro,ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù;ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko,wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.

11. Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dánígbà tí wọ́n bá gbẹ,àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná.Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá;nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn,Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn.

12. Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà,láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti,yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

13. Ní ọjọ́ náà,a óo fun fèrè ogun ńlá,àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiriaati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijiptiyóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Aisaya 27