Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 26:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”

7. Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodoó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.

8. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́.

9. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọnítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyéni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.

10. Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,kò ní kọ́ láti ṣe rere.Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.

11. OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà,ṣugbọn wọn kò rí i.Jẹ́ kí wọn rí i péọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún,kí ojú sì tì wọ́n.Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

12. OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia,nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa.

13. OLUWA, Ọlọrun wa,àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí waṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀.

14. Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́,ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú.Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà,o sì pa wọ́n run,o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé.

15. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,o sì ti buyì kún ara rẹ.

16. OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.

17. Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsíbẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.

Ka pipe ipin Aisaya 26