Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 26:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Àwọn òkú wa yóo jí,wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.

20. Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ inú yàrá yín,kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá.

21. OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀,láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde,kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 26