Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 26:15-20 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,o sì ti buyì kún ara rẹ.

16. OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.

17. Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsíbẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.

18. A wà ninu oyún, ara ń ro wá,a ní kí a bí, òfo ló jáde.A kò ṣẹgun ohunkohun láyébẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú.

19. Àwọn òkú wa yóo jí,wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.

20. Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ inú yàrá yín,kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá.

Ka pipe ipin Aisaya 26