Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 26:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà,orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:“A ní ìlú tí ó lágbára,ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.

2. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.

3. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun.

5. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,ó fà á sọ sinu eruku.

6. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”

7. Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodoó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.

Ka pipe ipin Aisaya 26