Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 26:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà,orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:“A ní ìlú tí ó lágbára,ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.

2. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.

3. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun.

5. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,ó fà á sọ sinu eruku.

6. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”

7. Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodoó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.

8. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́.

9. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọnítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyéni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.

10. Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,kò ní kọ́ láti ṣe rere.Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.

Ka pipe ipin Aisaya 26