Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 24:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn,wọ́n ń fi ògo fún Olódodo.Ṣugbọn èmi sọ pé:“Mò ń rù, mò ń joro,mò ń joro, mo gbé!Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.”

17. Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé.

18. Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá,yóo já sinu kòtò,ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtòyóo kó sinu tàkúté.Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí,àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì.

19. Ayé ti fọ́, ayé ti fàya,ayé sì mì tìtì.

20. Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí,ó ń mì bí abà oko.Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn,ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.

21. Ní àkókò náà,OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run;ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé.

22. A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n,wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n.Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n.

23. Òṣùpá yóo dààmú,ìtìjú yóo sì bá oòrùn.Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọbalórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu.Yóo sì fi ògo rẹ̀ hànníwájú àwọn àgbààgbà wọn.

Ka pipe ipin Aisaya 24