Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 23:8-18 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.

9. OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.

10. Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́.

11. OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkunÓ ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì.Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaanipé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run.

12. Ó ní, “Àríyá yín ti dópin,ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára.Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru,ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.”

13. Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro.

14. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi, nítorí àwọn ilé ìṣọ́ yín tí ó lágbára ti wó.

15. Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé:

16. “Mú hapu, kí o máa káàkiri ààrin ìlú,ìwọ aṣẹ́wó, ẹni ìgbàgbé.Máa kọ orin dídùn ní oríṣìíríṣìí,kí á lè ranti rẹ.”

17. Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè.

18. Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA.

Ka pipe ipin Aisaya 23