Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 23:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí:Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi;nítorí pé Tire ti di ahoro,láìsí ilé tabi èbúté!Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n.

2. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni;àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun,

3. wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,ìkórè etí odò Naili.Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé.

4. Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoninítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ríkì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”

5. Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijiptiàwọn ará Ijipti yóo kérora.

6. Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun.

7. Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!

8. Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.

9. OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.

Ka pipe ipin Aisaya 23