Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 18:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó ṣe,ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudaniibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀.

2. Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili,tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi.Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá,ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán,àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọnati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù.Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá,àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.

3. Gbogbo aráyé,ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè,ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.

4. Nítorí pé OLUWA sọ fún mi péòun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òunbí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.

5. Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.

Ka pipe ipin Aisaya 18