Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 16:6-14 BIBELI MIMỌ (BM)

6. A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.

7. Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,tí ó ní èso àjàrà ninu.

8. Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.

9. Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibumabí mo ṣe sọkún fún Jaseri;mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrònítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.

10. Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso;ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn.Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.

11. Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu,ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi.

12. Nígbà tí Moabu bá wá siwaju,tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀,títí ó fi rẹ̀ ẹ́,adura rẹ̀ kò ní gbà.

13. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí.

14. Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”

Ka pipe ipin Aisaya 16