Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 15:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.

5. Ọkàn mi sọkún fún Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu.

6. Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,koríko ibẹ̀ gbẹ;àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.

7. Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo.

8. Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan,ẹkún náà dé Egilaimu,ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu.

9. Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀,sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a.Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Aisaya 15