Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 14:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

24. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.

25. Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.

26. Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”

27. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣeta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?

28. Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:

29. Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.

30. Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.

31. Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè,kí ìwọ ìlú sì figbe ta.Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnìnítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá,kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọntí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.

32. Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini?A óo sọ fún wọn pé,“OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”

Ka pipe ipin Aisaya 14