Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 14:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára.

3. Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe,

4. ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé:“Agbára aninilára ti pinìpayà ojoojumọ ti dópin.

5. OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi,ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí

6. tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró,tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè,tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́.

7. Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafiawọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀.

8. Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín;àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé,‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀,kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’

Ka pipe ipin Aisaya 14