Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 14:16-29 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;

17. ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’

18. Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọnolukuluku ninu ibojì tirẹ̀.

19. Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.

20. A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù,nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run,o sì ti pa àwọn eniyan rẹ.Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!

21. Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ runnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn,kí wọn má baà tún gbógun dìde,kí wọn gba gbogbo ayé kan,kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.”

22. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn.

23. N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

24. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.

25. Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.

26. Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”

27. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣeta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?

28. Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:

29. Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.

Ka pipe ipin Aisaya 14