Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 14:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,‘N óo gòkè dé ọ̀run,n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.

14. N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,n óo wá dàbí Olodumare.’

15. Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;

17. ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’

18. Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọnolukuluku ninu ibojì tirẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 14