Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 14:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu.

2. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára.

3. Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe,

4. ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé:“Agbára aninilára ti pinìpayà ojoojumọ ti dópin.

5. OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi,ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí

6. tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró,tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè,tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́.

7. Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafiawọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀.

8. Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín;àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé,‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀,kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’

9. “Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé.Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ,àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn,Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.

10. Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé,‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà.Ẹ ti dàbí i wa.

11. A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú.Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lóríàwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’

12. “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run,ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀!Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀,ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí.

Ka pipe ipin Aisaya 14