Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 13:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrìayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀,nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru.

14. Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé,ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́;olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀,wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn.

15. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa,ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á.

16. A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn,a óo kó ilé wọn,a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára.

17. Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn,àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadakabẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí.Wọn óo wá bá Babiloni jà.

18. Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin,wọn kò ní ṣàánú oyún inú,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde.

19. Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé,ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea,yóo dàbí Sodomu ati Gomora,nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run.

20. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran,àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀.

21. Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí,ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀.

22. Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀,ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko,àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé,ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 13