Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 10:28-34 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,ó ti dé sí Aiati;ó kọjá ní Migironi,ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.

29. Wọ́n sọdá sí òdìkejì odòwọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.Àwọn ará Rama ń wárìrì,àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ.

30. Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,kí Anatoti sì dá a lóhùn.

31. Madimena ń sá lọ,àwọn ará Gebimu ń sá àsálà.

32. Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,àní òkè Jerusalẹmu.

33. Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.

34. Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí,Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó.

Ka pipe ipin Aisaya 10