Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 10:21-33 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára.

22. Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo

23. Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin.

24. Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín.

25. Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run.

26. Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti.

27. Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.”

28. Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,ó ti dé sí Aiati;ó kọjá ní Migironi,ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.

29. Wọ́n sọdá sí òdìkejì odòwọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.Àwọn ará Rama ń wárìrì,àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ.

30. Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,kí Anatoti sì dá a lóhùn.

31. Madimena ń sá lọ,àwọn ará Gebimu ń sá àsálà.

32. Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,àní òkè Jerusalẹmu.

33. Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 10