Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 10:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu,yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀.

13. Nítorí ó ní,“Agbára mi ni mo fi ṣe èyí,ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe énítorí pé mo jẹ́ amòye.Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada,mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn.Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin.

14. Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ.Mo kó gbogbo ayé,bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ,kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan,kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.”

15. Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ?Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi?Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́,tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́?

16. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirunsí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀.Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo,ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni.

17. Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná,Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná;yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.

18. OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run,yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso,bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan.

19. Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ.

20. Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́.

21. Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára.

22. Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo

23. Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin.

24. Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín.

25. Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run.

26. Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti.

Ka pipe ipin Aisaya 10