Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.

23. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.

24. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.

25. Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.

26. N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”

27. A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.

28. Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.

29. Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.

30. Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,ati bí ọgbà tí kò lómi.

31. Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná.Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.

Ka pipe ipin Aisaya 1