Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.

23. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.

24. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.

25. Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.

26. N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”

27. A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.

28. Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.

29. Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.

30. Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,ati bí ọgbà tí kò lómi.

Ka pipe ipin Aisaya 1