Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 9:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá íṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Ísírẹ́lì wá, àwọn ni Ísírẹ́lì:

7. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ: “Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀.”

8. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ.

9. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

10. Kì sì íṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa;

11. Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, (kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kòse ti ẹni tí ńpeni;)

12. A ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

13. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jákọ́bù ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kóríra.”

14. Njẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìsòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri!

Ka pipe ipin Róòmù 9