Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 9:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́. Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́. Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo. Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé.

6. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá íṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Ísírẹ́lì wá, àwọn ni Ísírẹ́lì:

7. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ: “Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀.”

8. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ.

9. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

Ka pipe ipin Róòmù 9