Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 9:22-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun;

23. Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo,

24. Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú?

25. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé,“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

26. Yóò sì ṣe,“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’níbẹ̀ ni a ó gbé ti sọ fún wọn pé,ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

27. Ìsáíà sì kí gbe nnítorí Ísírẹ́lì pé:“Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí bí iyanrìn etí òkun,apákan ni ó gbàlà.

28. Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

29. Àti bí Ìsáià ti wí tẹ́lẹ̀:“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọnỌmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,àwa ìbá ti dàbí Sódómù,a bá sì ti sọ wá dàbí Gòmórà.”

30. Ǹjẹ́ kílí àwa ó ha wí? Pé àwọn aláìkọlà, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá ni.

31. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo,

32. Nítorí kíni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ni;

33. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn subú kalẹ̀ ní Síónì,ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

Ka pipe ipin Róòmù 9