Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 9:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, kínni ó ha tún bá ni wí fún? Nítorí tani ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?

20. Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? Ohun tí a mọ, a máa wí fún ẹni tí ó mọ ọn pé, Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyì?

21. Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá?

22. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun;

23. Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo,

24. Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú?

25. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé,“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

Ka pipe ipin Róòmù 9