Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ìbátan mi nípa ti ara, ó wù mí púpọ̀ láti rí i pé ẹ gba Kírísítì gbọ́.

2. Ọkàn mi gbọgbẹ́, mo sì ń joró lọ́sán àti lóru nítorí yín.

3. Mo fẹ́ lọ sọ pé ó sàn fún mi kí a yọ orúkọ mi kúrò nínú ìwé Ìyè, kí ẹ̀yin lè rí ìgbàlà. Kírísítì pàápàá àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú mọ̀ pé òtítọ́ ọkàn mi ni èmi ń sọ yìí.

4. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti fi fún yín: Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ẹ kì yóò tẹ́tí sí i. Ó yàn yín bí ẹni ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀. Ó sìn yín (la ihà já) pẹ̀lú ìtànsán ògo rẹ̀, ó mú kí ó dá a yín lójú pé òun yóò bù kún yín, ó fi òfin fún yín kí ẹ le mọ ìfẹ́ rẹ̀ lójojúmọ́, ó yọ̀ǹda fún yín láti sin òun pẹ̀lú ìpinnu ńlá.

5. Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́. Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́. Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo. Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé.

Ka pipe ipin Róòmù 9